Bàbá Ìgbómìnà

Àgbéyẹ̀wọ̀ Bàbá Ìgbómìnà láti ọwọ́ọ Tọ́lání Awótáyọ̀

Bàbá Ìgbómìnà jẹ́ eré oníṣe láti ọwọ́ọ Tọ́lání Awótáyọ̀ tí ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé MAMSA Publishers tẹ̀ jáde lọ́dún 2006. Ìwé náà ṣàfihàn pàtàkì ìmúra ṣíṣẹ́ àti bí ó ṣe jẹ́ pé kò sí ẹnì tó mọ ọ̀la.

Kókó ọ̀rọ̀ tí ìwé yìí tẹnumo náà ni kí gbogbo ọmọ ẹ̀dá èèyàn múra ṣíṣẹ́. Ìwé náà tún jẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo ẹni tó ń lọ ilé yẹ̀míwò. Ó dá wọn lẹ́kun láti máa sáré kiri ilé àwọn aláwo, wòlíì, àti àfáà nítorí kò sí ẹnì tó mọ bí ọ̀la ó ti rí. Ìwé náà kógo já níbi ìṣàfihàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ pàápàá jù lọ ìwà ojúkòkòrò àti ìlara. Ìsọwọ́lò èdè ònkọ̀wé náà dára. Ó sì tún lò àwọn ọnà èdè àti òwe tó dára.

Àkópọ̀ Ìtàn

Gbádéyan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgìrìpá tó ń gbé ní Abà Asanlú. Bí ó tilè jẹ́ pé ó jẹ́ ẹni tí ó múra ṣíṣe, kò rọ́wọ́ horí. Nǹkan kò ṣẹnu re fún un rárá. Ọ̀rẹ́ rẹ kan tí ó ní láárí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sanmori ló ń jẹ kí ó rọ́wọ́ tí bọ ẹnu. Lọ́jọ́ kan, Sànmọ̀rí gbà á níyànjú pé kó sìn òun lọ ilé yẹ̀míwọ̀ pé òun fẹ́ ṣe àyẹ̀wò nípa ilé tí òun fẹ́ kọ́.

Nígbà tí wọ́n dé ilé awo Abésùjobì, Gbádéyan ni odù ifá tó kọ́kọ́ jáde báwí. Babaláwo ni kí ó dín kìràkìtà rẹ kú nítorí orí burúkú ní orí tí ó yàn wá ilé ayé, àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò gba ẹbọ kò sì gba ètùtù. Gbádéyan lórí òun kọ gbogbo ohun tí ifá sọ, ó sì bínú kúrò nílé awo.

Bàbá Ìgbómìnà
Front cover of Bàbá Ìgbómìnà by Tọ́lání Awótáyọ̀.

Sànmọ̀rí tún gbà á níyànjú pé káwọn lọ ilé Àfàá Tápà, bákan náà lọ̀rọ̀ rí. Àfàá ní orí burúkú ni Gbádéyan gbé wá sáyé. Gbádéyan tún bínú lọ ilé.

Nígbà tí ó délé, ó sọná sí abà oníkoríkò tó ń gbé àti àwọn nǹkan ìní rẹ. Ó sì forí lé Ilé Ifẹ̀, ó fẹ́ lọ pá ara rẹ̀. Gbogbo àrọwà tí Sànmọ̀rí pa fún un kò wọ etí rẹ.

Gbádéyan dé Ilé Ifẹ̀, ó ń wádìí ibi tí wọ́n ń pè ní Ọ̀gbọ́n Ìdó, ṣùgbọ́n àwọn àgbà ìlú tí di ihò náà pá ṣáájú àsìkò náà. Elútọ́lá, ẹni tó gba Gbádéyan sílé, pàrọwà fún un pé kí ó yí ìpinnu rẹ̀ padà lẹ́yìn ìgbà tí ó gbọ́ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀.

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ara Bàbá Ìgbómìnà (orúkọ tí wọ́n fún Gbádéyan ní Ifẹ̀) mọ ilé. Ó kókó ń ṣe iṣẹ́ àgbàṣe ní oko Elútọ́lá. Láìpé wón fún òun náà nílẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní dá ọkọ. Ọ̀rọ̀ rẹ tí d’yọ̀. Owó tí dé sí ọwọ rẹ. Ó ti ṣí sítọ́ọ̀ kòkó ńlá sí Ilé Ifẹ̀, kọ́lé, ó ra mọ́tò, kódà ó ti gbé ìyàwó tuntun pàápàá.

Nígbà tó yá, àwọn ènìyàn rẹ̀ nílé Ife ní kó nìṣó n’ilu rẹ pé àwọn fe lọ mọ̀ọ́ délédélé. Òkìkí kan lọ́jọ́ tí Gbádéyan wọ Ìsánlú. Nṣe lo ń fún tolórítẹlẹ́mù lọ́wọ́. Gbadeyan àti ọ̀rẹ́ẹ̀ rẹ Sanmori lọ kí babaláwo ọjọ́sí. Àwo Abesu sì ṣàlàyé pé ayanmo Gbadeyan yípadà nítorí pé ó fi ẹnu kò àsọtẹ́lẹ̀ tí ifá sọ sáyé rẹ̀ lójúẹsẹ.

A ríi ká ní ìran kefa pé inú Sanmori kò dùn bí àyípadà rere ṣe débá ìgbé ayé Gbádéyan. Rọ́lákẹ́, ìyàwó rẹ̀, kó igbó síi lórí pé orí rẹ ni Gbádéyan lò. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìlara ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó sì gbé owó fún àwọn àgbànipa láti dá èmi rè lègbodo.

Owó palaba àwọn panipani segi nígbà tí wọ́n délé Gbádéyan lóru. Ìyẹn fi gbetugbetu báwọn sọ̀rọ̀, ó ní kí wọ́n padà sí ilé ẹni tó rán wọn wá. Wọn padà sílè Sanmori, wọn si gba èmi rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ikú Sanmori dá wàhálà sáàárín ìlú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ara ilu ló rò wípé Ọba Ẹ̀lábíyìí lọ́wọ́ nínú ikú rẹ nítorí ìjà tí ń bẹ láàárín wọn. Ọba sì bínú wàjà. Ògunlápe tí í ṣe ọdẹ tó ń sọ ìlú ló wá ṣàlàyé pé òun rí Sànmọ̀rí lọ́gànjọ́ òrú tó lòun fẹ́ lọ gbé owó fún àwọn kan. Ó túbọ̀ ṣàlàyé pé ọba kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú ikú rẹ̀.

Ẹ̀dá Ìtàn Nínú Bàbá Ìgbómìnà láti ọwọ́ọ Tọ́lání Awótáyọ̀

Lára àwọn ẹ̀dá ìtàn tó wà nínú eré oníṣe lati rí Gbádéyan, Sànmọ̀rí, Èlútọ́lá, Ọba Ẹ̀lábíyìí,

Gbádéyan tí àwọn ènìyàn ń pè ní Bàbá Ìgbómìnà ní olú ẹ̀dá ìtàn. Ó tálákà ju èkúté ṣọ́ọ̀sì lọ. Lọ́jọ́ kan, ó tẹ̀lẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ ilé yẹ̀míwò wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sínú ayé rẹ̀ wípé orí burúkú lorí tó yàn wáyé. Ó bínú kúrò n’ilu, ó kọrí sí Ilé Ifẹ̀ pẹ̀lú èróngbà láti pa ara rẹ̀.

Ilé Ifẹ̀ ló ti ṣalábàápàdé àwọn aláàánú tí ó ràn án lọ́wọ́. Ibẹ̀ ni ayé rẹ̀ tí yí padà sí rere tó sì di olówó àti olókìkí.

Sànmọ̀rí ní ọ̀rẹ́ Gbádéyan tó ń ràn án lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan kò ì tíì ṣenure fún-un. Ó padà ń ṣe ìlara Gbádéyan nígbà tí ayé rẹ yí padà. Ibi tí ó ti ń pète-pèrò láti pa a ní òun gangan ti rí ikú he.

Ẹ̀lútọ́lá ni àgbè ọmọ Ilé Ifẹ̀ tí ó rán Gbádéyan lọ́wọ́ ní ìgbà tí ó wá ikú lọ sí Ilé Ifẹ̀. Ó gbà Gbádéyan sílé, ó tójú rẹ̀, ó sì fún un nílẹ̀ láti máa dá oko.

Abéṣù ni babaláwo tó ní orí burúkú ni Gbádéyan gbé wáyé.

Ọba Ẹ̀lábíyìí ni Asánlú ti ìlú Ìsánlú.

Rọláké ni ìyàwó Sànmọ̀rí.

Ògunlápe ni ọdẹ tó ń sọ ìlú.

Àfáà Tápà ni atẹyanrìn tí òun náà ní orí burúkú lórí tí Gbádéyan gbé wáyé.


Ka àròkọ yìí ní èdè gẹ̀ẹ́sì.

Similar Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.