Ìrìnàjò Sínú Ayédiméjì by Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀ is a sci-fi novel published by Dagok Limited in 2017. The book is the first science fiction work written in the Yoruba language. It thoughtfully explores the vital roles that faith, advanced knowledge, and technology can play in the growth and development of society.
Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀ skillfully weaves storytelling with deep insight. Apart from his fluent and expressive use of language, he also invents various Yoruba terms to explain complex scientific ideas in a way that is accessible and understandable to a broad audience.
Ìrìnàjò Sínú Ayédiméjì
Ìrìnàjò Sínú Ayédiméjì jẹ́ ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀geere tí Dagok Limited tẹ̀ jáde lọ́dún 2017. Ìwé náà jẹ́ ìwé fàbú ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ ní èdè Yorùbá. Ó sì kógo já níbi ṣàfihàn ipa pàtàkì tí ìgbàgbọ́ àti ìṣàmúlò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ le kó lórí ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè àwùjọ.
Ọ̀nkòwé náà gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ ó sì gbàwo bọ. Yàtọ̀ sí pé ìsọwọ́lò èdè rẹ̀ dára púpọ̀, ó tún ṣẹ̀dá oríṣiríṣi àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá láti ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́nà tó lè yé ẹnikẹ́ni yékéyéké.

Àkópọ̀ Ìtàn (Summary)
Ní orí Kínní, a rí pé ìdágìrì kan tí jí àwọn aráàlú Afimosoro. Ọkàn nínú àwọn òkè ńlá ńlá tó wà lágbègbè ìlú náà tí gbiná lórí. Odomodekunrin kan tí orúkọ re ń jẹ Dúródọgbọ́n pẹ̀lú àwọn òbí àti àwọn aráàlú tó kú péjọ sórí òkè kan. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ onikaluku wọn lóminú. Dúródọgbọ́n bèrè àwọn ìbéèrè nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́wọ́ bàbá rè ẹni tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Òyédìmọ̀. Bàbá kò sí lè dáhùn àwọn ìbéèrè náà dájúdájú. Èyí ló fà á tí bàbá rè fi rán sí àbúrò rẹ̀ tí í ṣe Bàbá Awámọ̀jìnlẹ̀ tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́-ìmọ̀. Bàbá yìí ló sì fún ní ìwé ìtàn aládùn ńlá kan tí ó ti ka ìtàn àwọn Ikọ̀ọ àwọn awámọ̀jìnlẹ̀ tó rin ìrìn àjò sínú gbangba òfuurufú. Ṣáájú àsìkò yìí ni ẹnìkan tí yọ́lẹ̀ wọ yàrá ìyáwèékà l’ọ́gànjọ́ òru tí ó sì ti fa abala kan yà nínú ìwé ọ̀hún lọ.
Ikọ̀ọ àwọn ògbóǹtarìgì awámọ̀jinlẹ̀ yìí rin ìrìn àjò lọ sí inú òṣùpá olúpobíírí ayíbiiri kan tí wọ́n pè ní Ayédiméjì. Ó yà àwọn awámọ̀jinlẹ̀ náà lẹ́nu wípé òṣùpá yìí fara jọ ilé ayé púpọ̀. Wọ́n rí àwọn ohun abẹ̀mí nínú rẹ àti ilé gbigbe tí ó ní àwọn odò ńlá ńlá. Àwọn ìkọ́ awámọ̀jinlẹ̀ yìí kan ẹ̀ẹ̀mọ̀ níbi tí wọ́n tí ń ṣe ìwádìí kiri nínú Ayédiméjì. Mẹ́ta nínú wọn ló sì pàdánù èmi wọn.
Àwọn awámọ̀jinlẹ̀ ṣalábàápàdé oríṣiríṣi ohun àjòjì níbi tí wọ́n tí ń wá ọ̀nà kiri láti padà sí ilé ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló sì ṣègbé sínú ọ̀sálálu. Níbi ọ̀nà wíwá yìí náà ni wọ́n tí sọnù sínú àtijọ́. Wọ́n já sí ayé ti kò ì tíì yí dé sànmọ́nì tiwa. Wọn ṣalábàápàdé àwọn agánnnigàn; wọ́n sì rí àwọn oríṣiríṣi ẹranko, igi, ẹyẹ, àti kòkòrò tí won tí kú akúrun kí ó tó di ìgbà ayé tiwa.
Nígbẹ̀yìn tí ara awámọ̀jinlẹ̀ tí mọ́lé, wọn pínnu láti kọ àwọn agánnigan ní ìmọ̀ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Wọ́n dá ìlú tuntun tí wọ́n sọ ní Òde-Afìmọ̀ṣọrọ̀ sílẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn agánnigàn. Ọba Òyèdìmọ̀ fi ìṣo kọ nǹkan kan sí ara òpó rìbìtì kan gẹ́gẹ́ bíi ìfiránṣẹ́ sí àwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la. Olówa náà ri ìwé-ìtàn nípa ìrìn-àjò wọn mọ́lẹ̀ lábé ihò òkúta kan níbi kan tí wọ́n ń pè ní Ìgbàlẹ̀-Ayé.
Ní abala tó di àfẹ́kù tó gbẹ̀yìn, a rí wípé Dúródọgbọ́n, Bàbà Awamojinle àti Lógunlékòó padà ṣàwárí ìṣo ara òpó rìbìtì tí àwọn awámọ̀jìnlẹ̀ fi ránṣẹ́ sí ọ̀la.
Ẹ̀dá Ìtàn (Characters)
- Dúródọgbọ́n – Ọmọdékùnrin tó fẹ́ràn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.
- Bàbá awámọ̀jìnlẹ̀ – Àbúrò Òyèdìmọ̀, bàbá Dúródọgbọ́n. Ohùn náà jé onífẹ̀ẹ́-ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.
- Aláwòfín – Adarí ikọ̀ọ àwọn ònímọ̀ ìjìnlè tó lọ sí ìrìn-àjò sínú Ayédiméjì.
- Ọlọ́wà – Oníròyìn tó bá àwọn ònímọ̀-ìjìnlẹ̀ lọ ṣí ìrìn àjò sínú Ayédiméjì.
- Bínúpọ̀tá – Akíkanjú ọkùnrin tí ó jẹ́ ológun.
- Fìmọ̀ṣewà – Obìnrin kan ṣoṣo tó wà láàárín àwọn ikọ̀ọ àwọn ònímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà. Ó láyà bíi kìnnìún ó sì mọ ìṣirò dojú àmì.
Àwọn ẹ̀dá ìtàn mìíràn nii Aríwòye, Olómiró, Àwòjá, Lógunlékòó, Fínnílàáwò, abbl.
Where to Buy Ìrìnàjò Sínú Ayédiméjì
You can purchase either digital or physical copies of Bọ̀dé Ọ̀jẹ̀’s sci-fi novel from Alamoja’s Language And Cultural Store:
Alternative Spellings
Here are the alternative spellings, mostly anglicised, of the keywords, having been stripped of their diacritic marks:
- Irinajo Sinu Ayedimeji by Bode Oje
- Irinajo Sinu Ayedimeji
- Bode Oje
