Eégún Aláré is a play that tells the story of Ọ̀jẹ́làdé, a humorous masquerader, and the pranks he played. The book was written by the late Láwuyì Ògúnníran. It was first published for sale in 1969, and the publishing company Macmillan later republished it in 1972.
In this post, we shall examine the plot summary of Eégún Aláré by Láwuyì Ògúnníran.
Àkópọ̀ Ìtàn Eégún Aláré (Plot Summary of Eégún Aláré)

Apá Kìíní
Ìwé náà fí mọ̀ wá wípé Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká àti Dáṣọfúnjó jé ọ̀rẹ́, wọ́n ń gbé Òkehò, eégún aláré sì ni àwọn méjèèjì. Nígbà tó ṣẹ, Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká pinu láti ṣe ìrìn-àjò lọ sí ìlú mìíran níbi tí aré eégún ti máa tà dáadáa. Ó gba ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀, Dáṣọfúnjó, ní ìyànjú láti tẹ̀lé òun lọ sùgbọ́n Dáṣọfúnjó kọ̀. Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká rọ Dáṣọfúnjó láti máa bá òun (Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká) ṣe ìtọ́jú ìyàwó òun, Ìyádùnńní, ẹni tó wà nínú oyún nígbà náà, Dáṣọfúnjó sì ṣe ìlérí láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ṣe ìlérí fún ìyàwó o rẹ̀ pé tí òun bá ti rí ibi jókòó níbi tí òun lọ, òun máa wá mú u kí oló tó di ìgbà tí yóò bímọ. Ó dágbéré fún ìyàwó o rẹ̀, ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ àti àwọn ẹbí i rẹ̀, ó sì lọ.
Dáṣọfúnjó àti ìyàwó o rẹ̀ ń ṣe ìtọjú Ìyádùnńní, gẹ́gẹ́ bí Dáṣọfúnjó ṣe ṣe ìlérí. Ṣùgbón àárò ọkọ rẹ̀ sì ń sọ Ìyádùnńní. Pàápàá nígbà tí oṣù kan kọjá tí wọ́n kò gbúròó Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká. Dáṣọfúnjó àti ìyàwó rẹ̀ sáà ń fi Ìyádùnńní lọ́kàn balẹ̀ títí tó fi bímọ. Àwọn ará ilé Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká àti Dáṣọfúnjó pohùnpọ̀ láti sọ ọmọ náà ní Ọ̀jẹ́làdé. Wọ́n wo ẹsẹ̀ǹtayé ọmọ náà, babaláwo sì sọ fún wọn pé iṣẹ́ tí bàbá ọmọ náà ń ṣe ni ọmọ náà máa ṣe, àti pé ó máa làmì-laka ní ìdí iṣẹ́ náà ju bàbá a rẹ̀ lọ.
Nígbà tí ọdún mẹ́wàá pé léyìn tí Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ti lọ ìrìn-àjò tí kò sí padà dé, ìyàwó o rẹ̀, Ìyádùnńní, pinu láti wá a lọ. Ó fí ọ̀rọ̀ yí tó ọ̀rẹ́ ọkọ rẹ̀, Dáṣọfúnjó, létí. Dáṣọfúnjó àti ìyàwó o rẹ̀ gbìyànjú láti yí Ìyádùnńní lọ́kàn padà. Wọ́n sàlàyé fún un pé kò rọrùn láti máa wá èèyàn káàkiri nígbà tí a kò mọ pàtó ibi tí onítọ̀hún wà. Ṣùgbón ó takú délẹ̀. Ìyàwó o Dáṣọfúnjó tún sọ pé tí yóò bá tiẹ̀ lọ, kó fi ọmọ rẹ̀, ìyẹn Ọ̀jẹ́làdé, ẹni tó ti lé ní ọdún mẹ́sàn-án, tìwọ́n nílé. Ṣùgbón Ìyádùnńní tún kọ̀ jálẹ̀. Dáṣọfúnjó sàdúrà fún tìyá tọmọ, ó sì fún wọn lówó kí wọ́n tó máa lọ.
Ìyádùnńní àti ọmọ rẹ̀ rìn káàkiri láti abúlé dé abúlé, ìletò dé ìletò àti ìlú dé ìlú ṣùgbọ́n wọ́n kò rí eégún tí ń jẹ́ Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká. Lẹ́yìn bí i ọdún kan, tí owó ti ń tán lọ́wọ́ ọ wọn, wọ́n pinu láti dúró ṣiṣẹ́ ní ìlú kan kí àwọn le rí owó tí àwọn yó fi máa bá ìrìn-àjò wọn lọ. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ àárù títí tí wọ́n fi rí owó díẹ̀ kó jọ. Ìgbà yìí ni wọ́n pinu àti padà sílé. Wọ́n délé, wọ́n lọ sí ọ̀dọ Dáṣọfúnjó tààrà, wọ́n sì ro gbogbo ohun tí ojú u wọn rí fún Dáṣọfúnjó. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká mú Ọ̀jẹ́làdé lọ sí ọ̀dọ Dáṣọfúnjó pé kó kọ́ ọ ní idán pípa. Dáṣọfúnjó fi ọdún mẹ́ta kọ́ ọmọ náà ní iṣẹ́, ó mọ iṣẹ́ náà. Wọ́n sàdúrà fún un. Ọ̀jẹ́làdé pinu láti wá ire tirẹ̀ lọ sí ìlú mìíran. Dáṣọfúnjó gbìyànjú láti yíi lọ́kàn padà ṣùgbọ́n kó gbà. Dáṣọfúnjó fa ọmọ rẹ̀, Àǹséétù, fún Ọ̀jẹ́làdé, gẹ́gẹ́ bíi ìyàwó, ó súre fún un, Ọ̀jẹ́làdé sì bá tirẹ̀ lọ. Òun àti ìyàwó o rẹ̀ àti àwọn ọmọṣẹ́ rẹ̀ fi ìlú kan ṣe ìbùgbé, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti máa ń lọ sí àwọn ìlú mìíran lọ ṣeré.
Baálẹ̀ ìlú kan ránṣẹ́ sí Ọ̀jẹ́làdé láti wá ṣeré fún òun. Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà, Ọ̀jẹ́làdé pẹ̀lúu ìyàwó o rẹ̀ lọ kí eégún aláré tó wà ní ìlú náà láti gba ìyọ̀ǹda láti ṣeré. Bàbá yìí fún un ní ìyọ̀ǹda ṣùgbọ́n Àǹséétù, ìyàwó o Ọ̀jẹ́làdé, wọ bàbá yìí lójú. Ní ọjà alẹ́, bàbá yìí da ẹnu ìfẹ́ kọ Àǹséétù ṣùgbọ́n Àǹséétù kọ̀. Àǹséétù rò fún ọkọ rẹ̀ nígbà tó délé. Ọkọ rẹ̀ lọ bá bàbá yìí, bàbá sì parọ́ pé òun kò mọ̀ pé ìyàwó Ọ̀jẹ́làdé ni. Lọ́jọ́ eré, Ọ̀jẹ́làdé pitú ọwọ́ ọ rẹ̀. Ó pe ẹ̀sà, ó parada, ó di òyìnbó, ẹkùn àti àwọn nǹkan mìíràn. Lẹ́yìn náà, ó di òjòlá. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí ó yẹ kí Ọ̀jẹ́làdé ti di èèyàn padà tí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ síní jà ràpà nílẹ̀. Ọ̀jẹ́làdé ò le di èèyàn mọ́. Àwọn ọmọṣẹ́ rẹ̀ sì ń sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá wà nídìí ọ̀ràn náà kó jáwọ́. Àwọn òǹwòran bẹ̀rẹ̀ síní túká léní èjì. Ọ̀jẹ́làdé ki ẹnu bọ ẹ̀sà, ó ń sọ nípa ìtàn ayé e rẹ̀. Nínú u rẹ̀ ni ó ti dárúkọ pé Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ni bàbá òun. Bàbá eégún aláré ìlú yìí tó fẹ́ fẹ́ Àǹséétù sáré jáde, tó sì ń sọ pé òun fi ọwọ́ ara òun ṣe ará òun, pé ọmọ òun ni òun fi oògùn ṣe níkà. Àṣé bàbá yìí ni Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká tó lọ ìrìn-àjò àìdé. Kíá, Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká ṣètò ẹ̀rọ̀, Ọ̀jẹ́làdé sì di èèyàn padà. Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká fí ẹ̀sà dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ Baálẹ̀, òun àti ọmọ rẹ̀ àti ìyàwó ọmọ rẹ̀ àti àwọn ọmọṣẹ́ sì kọrí sí ìlú u wọn.

Apá Kejì
Lẹ́yìn tí wọ́n dé ìlú u wọn, Ọ̀jẹ́làdé ti ń múra àti lọ ṣeré ní ìlú mìíran ni bàbá a rẹ̀, Ọ̀jẹ̀ Lárìnnàká, bá ta téru nípàá. Lẹ́yìn tí ó ṣe òkú tán, ó ṣe ìrìn-àjò rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìlú kan báyìí láti ṣeré, ó yapa ìṣe àwọn eégún aláré, kó júbà ẹnikẹ́ni tó fi bẹ̀rẹ̀ eré. Ó gbójú lé àwọn oogùn tí bàbá a rẹ̀ fún un kó tó papòdà. Ó ń ṣeré lọ, ó ń pẹ̀sà. Ó ṣe èyí títí tí Baálẹ̀ ìlú náà fi bùn ún ní owó àti ọmọbìnrin kan gẹ́gẹ́ bíi ìyàwó. Ọ̀jẹ́làdé dúpẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ síní pidán. Orí èyí ló wà tí àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ ìlú náà fi ránṣẹ́ sí i pé kí nìdí tí kò fi júbà àwọn kó tó bẹ̀rẹ̀ eré. Kàkà kí Ọ̀jẹ́làdé tọrọ àforíjìn, ńṣe ló gbójú agan sí wọn. Àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ náà déte Ọ̀jẹ́làdé ní kọ̀rọ̀, ó paradà di ọ̀ni níbí tó ti ń ṣeré, kò sì le di èèyàn mọ́. Ó fí ẹ̀sà sọ fún ọmọ́ṣẹ́ ẹ rẹ̀ tí ń jẹ́ Ọ̀jẹ́kúnlé pé àdó kan wà tí bàbá òun so mọ́ àjà ní ìlú u wọn tí ẹ̀rọ̀ wá nínú u rẹ̀; kí Ọ̀jẹ́kúnlé lọ mú àdó náà wá. Ọ̀jẹ́kúnlé sáré lọ. Tohùn tẹnu rẹ̀, òjò bẹ̀rẹ̀. Àwọn òǹwòran àti àwọn ọmọṣẹ́ Ọ̀jẹ́làdé yòókù ti sá sí abẹ́ ilé, ó kú Ọ̀jẹ́làdé nínú òjò. Nígbà tí òjò náà pọ̀, àgbàrá òjò wọ́ òni náà lọ sínú odò ńlá kan tí ó jásí ìlú mìíran. Ọ̀jẹ́làdé tíí ṣe òní dúró sí etí odò. Ibí ló wà tí ó rí obìrin kan tó ru agbọ̀n tó ń bọ́, ó fi ẹ̀sà bá obìrin náà sọ̀rọ̀. Nígbà tí obìrin yìí rí òni tó ń pẹ̀sà bíi ènìyàn, ó fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ, agbọ̀n orí i rẹ̀ sì jábọ́. Bí èèrí tó wà nínú u agbọ̀n náà ṣe dà sí òni lára ni ó yípadà tó di Ọ̀jẹ́làdé nínú u ẹ̀kú eégún. Ọ̀jẹ́làdé tẹ̀lé obìrin yìí lọ ilé, ó ṣàlàyé e bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ fún obìrin yìí àti ọkọ rẹ̀. Ọkọ obìrin sì yìí fún Ọ̀jẹ́làdé ní ẹ̀wù àti ṣòkòtò tó wọ̀ lọ́ sí ìlú u rẹ̀.
Apá Kẹta
Òkìkí i Ọ̀jẹ́làdé kàn káàkiri tilé toko gẹ́gẹ́ bí i akọni aláré. Òkìkí i rẹ̀ kàn títí dé ọ̀dọ Aláàfin Ọ̀yọ́. Aláàfin ránṣẹ́ sí Ọ̀jẹ́làdé pé kí òun àti gbajúmọ̀ aláré mìíràn tí ń jẹ́ Dúdúyẹmí jọjọ wá faga-gbága lọ́dọ́ òun kí òun sì fi ẹni tó bá borí jẹ Baálẹ̀ Arẹ̀kú-Eégún. Ìyàwóo Ọ̀jẹ́làdé kékeré bẹ ọkọ rẹ̀ pé kí ọ̄ má lọ àti pé kí ó pa iṣẹ́ idán pípa tì pátápátá. Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ dáhùn pé iṣẹ́ ẹ bàbá òun kò le hun òun àti pé ìpè ọba kì í ṣe ìpè tí èèyàn máa kọ̀. Òun àti ìyáálé rẹ̀, Àǹséétù, àti àwọn ọmọṣẹ́ rẹ̀ sì lọ sí Ọ̀yọ́.
Lọ́jọ́ eré, Aláàfin fi yé wọn pé kìí ṣe bí wọ́n ṣe le pidán tàbí tàkìtì ni òun fẹ́ wò láti fi mọ ọ̀gá bí kìí ṣe ẹ̀sà pípé, orin àti ijó o wọn. Àwọn òǹwòran ti pé síbẹ̀ láti tòsí àti jìnàjìnà. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀. Ọ̀jẹ́làdé fi ẹ̀sà júbà, Dúdúyẹmí náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀jẹ́làdé fi ẹ̀sà sọ àwọn itú tí òun ti pa, lẹ́yin náà, ó dá orin, òun àti ìyàwóo rẹ̀ sì jó sí i. Dúdúyẹmí ṣe bákan náà. Lẹ́yìn èyí, Dúdúyẹmí ní kí Ọ̀jẹ́làdé ki Ológbùró fún òun, Ọ̀jẹ́làdé sì kì í délẹ̀. Ó ké sí Dúdúyẹmí láti dáhùn ìbéèrè nípa ìtàn Ológbùró, Dúdúyẹmí sì ṣe bẹ́ẹ̀. Dúdúyẹmí náà tún na ìbéèrè sí Ọ̀jẹ́làdé, Ọ̀jẹ́làdé tún fi ẹ̀sà dáhùn. Wọ́n ṣe báyìí títí. Ọba pè wọ́n, ó sì kan sárá sí wọn. Ṣùgbọ́n ọ̀mì ni wọ́n ń ta, wọ́n sì ní láti mọ ọ̀gá. Torí i rẹ̀, Ọba sọ fún wọn pé kí wọ́n wá ohun mìíràn ṣe.
Dúdúyẹmí ni ó bẹ̀rẹ̀. Ó fi ẹ̀sà bú Ọ̀jẹ́làdé pàápàá nípa pé Ọ̀jẹ́làdé ti fi àwọn ìgbà kan jẹ́ ẹranko. Ọ̀jẹ́làdé náà fi ẹ̀sà dáhùn pé Àmọ̀ó tíí ṣe bàbá a Dúdúyẹmí ti fi ìgbà kan di màlúù, tí ó sì wọ igbó lọ ní àwọ̀rá. Ó ní òun ni Dúdúyẹmí náà fi ń ṣe bíi màlúù. Dúdúyẹmí sa òògùn sí Ọ̀jẹ́làdé, lẹ́yìn náà ó pe Ọ̀jẹ́làdé láti tún ìtàn náà sọ. Bí Ọ̀jẹ́làdé ti gbẹ́nu sókè láti pẹ̀sà, ń ṣe ni ó ń gbó bí i ajá. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rí báyìí, ìyàwó o rẹ̀ yọ òògùn jáde, ó pe ọfọ̀ sí i, Ọ̀jẹ́làdé sì bẹ̀rẹ̀ síní pẹ̀sá bí i èèyàn padà. Ó ní kí Dúdúyẹmí ki Ìyẹ̀rú Ọ̀kín Ọlọ́fàmọjọ̀ fun òun. Ṣùgbọ́n bí Dúdúyẹmí ṣe ní kí òun tẹnu bọ oríkì ni ó bẹ̀rẹ̀ síní húkọ́, tí ẹ̀jẹ̀ sì ń dà lẹ́nu rẹ̀. Ìyàwóo rẹ̀ àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lo oríṣìíríṣìí egbòogi fún un ṣùgbọ́n kò rọ̀ ọ́. Ijó tí Ọ̀jẹ́làdé àti ìyàwóo rẹ̀ ń jó ni àwọn èèyàn ń wò, kò sẹ́ni tó rójú u ti Dúdúyẹmí. Nígbà tó ṣẹ, Ọba fa Ọ̀jẹ́làdé lọ́wọ́ sókè,ó sì fi jẹ Baálẹ̀ Arẹ̀kú-Eégún. Oba wá ní kí Ọ̀jẹ́làdé bá òun yọ̀ǹda Dúdúyẹmí kó má baà kú. Ọ̀jẹ́làdé pẹ̀sà, lẹ́yìn náà ó kọrin. Bí Dúdúyẹmí ṣe gbádùn ni ó dìde tí ó sì darapọ̀ mọ́ Ọ̀jẹ́làdé nínú ijó o rẹ̀. Ọba pàṣẹ fún Dúdúyẹmí láti dọ̀bálẹ̀ fún Ọ̀jẹ́làdé, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n jó, wọ́n yọ̀, Ọ̀jẹ́làdé sì fi ẹ̀sà dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ Ọba. Lẹ́yìn náà, oun àti àwọn èèyàn rẹ̀ sì lọ sílé. Nígbà tí wọ́n délé, ó lọ jábọ̀ fún Baálẹ̀ ìlú u wọn àti àwọn eégún alárè yòókù, gbogbo wọn sì kan sárá sí i. Ọ̀jẹ́làdé darí sílé, àwọn èèyàn sì lọ kí i.
Lẹ́yìn èyí, Ọ̀jẹ́làdé ò lọ sí òde idán mọ́. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ló ń lọ tí wọ́n sì máa ń jábọ̀ fún un. Ó di oníṣòwò, ó sì ń gbé ayé ìrọ̀rùn.