Àlọ́ Àpagbè

Overview

Àlọ́ Àpagbè is a collection of folktales, as its title suggests. It was written by Adébísí Àmọ̀ó in 1978 and was published by the Evans Brothers printing house in 1987. The book was written with the mindset that it was possible to find characters in folklore who represented both human behaviour and traits, like Ìjàpá. This explains why other animals and even human characters become the central figures in the tales within this book instead of the traditionally known Ìjàpá. Out of the thirty-nine fables in the book, only one features Ìjàpá.

Àlọ́ Àpagbè

Àlọ́ Àpagbè jẹ́ ìwé àkójọpọ̀ àwọn àlọ́ àpagbè, gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀ ṣe fi hàn. Adébísí Àmọ̀ó ni ó kọ ìwé náà ní ọdún un 1978, ilé-iṣẹ́ atẹ̀wétà Evans Brothers sì bá a gbé e jáde ní ọdún 1987.

Òǹkọ̀wé sọ nínú u Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ ìwé náà pé ohun tó ṣe sábàbí kíkó àwọn àlọ́ náà jọ ni pé òun àti àwon akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ wòye pé ó ṣeéṣe kí á rí àwọn olú ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n fi ìwà àti ìṣe jọ Ìjàpá. Torí i rẹ̀, àwọn ẹranko mìíràn àti àwọn èèyàn ni wọ́n jẹ́ olú ẹ̀dá-ìtàn nínú àwọn àlọ́ inú ìwé yìí dípò Ìjàpá tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nínú u àlọ́ mẹ́tàdínlógójì tó wà nínú ìwé náà, àlọ́ kan péré ni Ìjàpá wà nínú u rẹ̀.

Àlọ́ Àpagbè

Ìfáàrà

Oríṣìríṣìí àlọ́ ló wà nínú ìwé náà. Púpọ̀ nínú àwọn àlọ́ náà gbé e jáde pé ìwà ìbàjẹ́ kò sunwọ̀n. Wọ́n máa fi ẹni tó ṣe ìwà ìbàjẹ́ han àti ohun tó tẹ̀yìn-in rẹ̀ jáde. Irú àwọn àlọ́ wọ̀nyí ló pọ̀ jù nínú ìwé náà. Èyí jẹyọ nínú àwọn àlọ́ bíi Ọláilo àti Iwin, Adìẹ àti Àdàbà, Ọmọ Elétí-Kunkun, Ìyá Arúgbó Kan àti Ọmọ Ìyá Mẹ́ta, Molọ́lájùwọ̀n àti Ìyáálé Rẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lódì kejì, àwọn àlọ́ mìíràn kọ́ wa pé ìwà rere ló tọ́. Àwọn àlọ́ bíi Bí Àkùkọ ṣe fẹ́ Ọmọ Ọba, Àwọn Orogún Méjì àti àwọn mìíràn.

Irú àlọ́ kẹta tó wà nínú ìwé náà ni àwọn àlọ́ tó ń sọ ìdí tí àwọn nǹkan kan fi rí bí wọ́n ṣe rí. Irú àwọn àlọ́ bíi Bí Ẹnu Àparò ṣe di Kúńbọ́, Ìdí tí Òjò fi jẹ́ Ọkọ Àgbàdo, Ajá àti Ọ̀kẹ́rẹ́, Ìdí tí Àwọn Abàmì Ọmọ fi wà àti Ìdí tí Imọ̀ Orí Ọ̀pẹ fi Lẹ́wà.

Kókó-ọ̀rọ̀

  1. Ìwà Rere
  2. Ìwà Búburú
  3. Olè
  4. Ọ̀kánjúà
  5. Ìkà
  6. Ilẹ̀ Dídà
  7. Àìmoore

Ẹ̀dá-ìtàn

Oríṣìríṣìí ẹranko àti èèyàn ló kópa nínú ìwé náà. Kò sí ọ̀kankan tí a le pè ní olú ẹ̀dá-ìtàn ṣùgbọ́n àwọn ẹranko kan hàn nínú àlọ́ méjì sí mẹ́ta. Àwọn ni Adìẹ, Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ajá.

Àwọn ẹranko mìíràn tó wà nínú ìwé náà ni Ìjàpá, Àṣá, Ọmọnílé, Ọ̀bọ, Àdàbà, Àparò, Ìgbín, Àgùntàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn èèyàn náà kópa, àwọn tó lórúko bíi Ọláilo, Molọ́lájùwọ̀n, Ṣáwẹ́roro, Olúrónbí, Fèré àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mìíràn kò sì lórúkọ.

Alternative Spellings

Here are the alternative spellings, mostly anglicised, of the keywords, having been stripped of their diacritic marks:

  • Alo Apagbe
  • Adebisi Amoo
  • Alo Apagbe by Adebisi Amoo
Reference
Abimbola, Waliyullah. (2025). Àlọ́ Àpagbè láti ọwọ́ọ Adébísí Àmọ̀ó. Litireso Yoruba. https://litiresoyoruba.com/alo-apagbe-lati-owoo-adebisi-amoo/ (Accessed on August 27, 2025 at 11:04)

Similar Entries

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.