Àgbéyẹ̀wọ̀ Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Ìyálóde Ìbàdàn láti ọwọ́ọ Akínwùmí Ìṣọ̀lá
Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Ìyálóde Ìbàdàn jẹ́ eré oníṣe láti ọwọ́ọ Akínwùmí Ìṣọ̀lá tí University Press PLC tẹ̀ jáde ní ọdún 1970. Ìwé náà ṣe àfihàn eewu ìwà ìkà lórí àwùjọ láti ara ìgbésí ayé Ẹfúnṣetán Aníwúrà tí í ṣe Ìyálóde kejì nínú ìtàn ìṣẹ́dálẹ̀ Ìbàdàn.
Lára kókó-ọ̀rọ̀ nínú eré oníṣe yìí lati rí ìwà ìkà, ṣísi-agbára-lò, ìkonilẹ́rú, ìfẹ́, àti ìdájọ àjùmọ̀ṣe.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti gbé eré oníṣe yìí jáde ní orí-ìtàgé ní ọ̀pọ̀ ìgbà, Túndé Kèlání ni ó ṣọ ọ́ di fíìmù àgbéléwò ní ọdún 2005. Pamela J. Smith sì túmọ̀ rẹ̀ àti eré oníṣe mìíràn tí Akínwùmí Ìṣọ̀lá kọ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún tó tẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bíi Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Ìyálóde Ìbàdàn and Tinúubú, Ìyálóde Ẹ̀gbá.
Àkópọ̀ Ìtàn
Ìbùdó ìtàn jẹ́ ìlú Ìbàdàn ní ìgbà ìwáṣẹ̀. Ààrẹ Látòósà ni olórí Ìbàdàn ní àsìko yìí, tí Ẹfúnṣetán sì di ipò Ìyálóde Ìbàdàn mú. Ẹfúnṣetán ni ẹnìkejì tó máa jẹ oyè yìí nílẹ̀ Ìbàdàn.
Ẹfúnṣetán jẹ́ olówó, ọlọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni, bọ̀rọ̀kìní ni láwùjọ. Àmọ́, kiní kan ba Àjàó jẹ́; apá rẹ̀ gùn ju itan lọ. Ẹfúnṣetán kò ní ọmọ tó lè pè ní tirẹ̀. To rí náà, ó ń ṣe ohun tó wù ú pẹ̀lú ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ẹrú tó ní. Àrà tó wù ú ló ń fi wọ́n dá. Bí o ṣe ń pa kékeré inú wọn, bẹ́ẹ̀ ló ń pa àgbà ààrin inú wọn.

A rí i kà ní Ìran Kẹrin pé ó pa “ọmọge mẹ́tàlá àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n” ní ìdunta. Ọ̀kan lára àwọn ẹrú rẹ̀ ṣe àpèjúwe bí “àgbàrá ẹ̀jẹ̀ tí ńṣàn lágbàlá, tí orí omidan ńyì gbiiri bí orí ẹ̀ran; tí ọrùn gìrìpá wá dàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ lẹ́nu idà olójúméjì.”
Àsùnwọ̀n Ẹfúnṣetán kún nígbàtí ó bẹ abẹ́nilórí lọ́wẹ̀ láti bẹ́ orí ọ̀kan lára àwọn erúbìnrin rẹ̀ tó lóyún. Gbogbo ìlú ló bẹ̀ ẹ́ tì. Níṣe ló ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀. Ó gé orí Adétutù toyún-toyún. Gbogbo ìlú bá dìde ogun sí i. Wọ́n kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú Ààrẹ Látòósà láti jẹ ilé rẹ̀ run.
Ẹfúnṣetán bá di ẹlẹ́yà, ẹni ìlẹ́lẹ̀ látara àsìlò agbára, àti ìwà ìkà. Ó di ẹni tó gbé májèlé jẹ nígbà tí kò rí ara gba àjàgà ẹ̀sín tí ìwà àti ìṣe rẹ̀ fà sí i lọ́rùn.
Ẹ̀dá Ìtàn
Lára àwọn ẹ̀dá ìtàn tó wà nínú eré oníṣe yìí lati rí Ìyálóde Ẹfúnṣetán, Àjílé, Adétutù, Ìtáwuyì àti Ààrẹ Látòósà.
Ìyálóde Ẹfúnṣetán Aníwúrà ni olú ẹ̀dá ìtàn. Bótilẹ̀jẹ́pé akọni obìnrin ni, ìwà ìkà àti ìṣi-agbára-lò fa ìsubú rẹ̀ nínú eré oníṣe yìí.
Àjílé ni ọ̀rẹ́ àtikékeré Ẹfúnṣetán tó salamí fún un nípa bí gbogbo ìlú ṣe ń kó ogun bọ̀ wá bá a.
Adétutù ni erúbìnrin tí wọ́n gé lórí toyún-toyún.
Ìtáwuyì ni ẹrúkùnrin tí ó fún Adétutù lọ́yún. Òun náà fi ikú sèfàjẹ látara ìgbìyànjú rẹ̀ láti dá ẹ̀mí Ẹfúnṣetán légbodò.
Ààrẹ Látòósà ni olórí àwọn ìjòyè Ìbàdàn. Ó ṣe atọ́nà bí wọ́n ṣe kápá Ẹfúnṣetán.