Àgbéyẹ̀wọ̀ Ìjàpá Tìrókò Ọkọ Yánníbo láti ọwọ́ọ Ọlágòkè Òjó
Ìjàpá Tìrókò Ọkọ Yánníbo jẹ́ àkójọpọ̀ ogún ìtàn àròsọ kéékèèké tó wá láti ọwọ́ọ Ọlágòkè Òjó, tí Learn Africa Plc sí kọ́kọ́ gbé jáde ní ọdún un 1973. Àwọn ìtàn náà dá lóríi Ìjàpá àti awon ẹranko mìíràn tàbí àwọn èèyàn. Àwọn ìtàn yìí gbé ìkà, ọ̀kanjúà àti ọgbọn àrékérekè tí Ìjàpá fi ba àwọn ẹ̀dá-ìtàn yòókù lò jáde. Ògbéni Ọlágòkè Òjó sọ nínú u Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ ìwé náà pé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń fẹ́ láti kọ́ èdè Yorùbá, àwọn tó ń fẹ́ ìtàn àròsọ apanilẹ́rìn-ín àti àwọn tó ń fẹ́ ìtàn tíí kọ́ni bí a ṣe ń kọ Yorùbá dáadáa ni àwọn ṣe kọ ìwé náà.

Ìfáàrà
Ìjàpá kópà nínú u gbogbo ogún ìtàn tó wà nínú ìwé náà. Kò sí ọ̀kankan nínú àwọn ìtàn náà tí Ìjàpá kò ti hu ìwà ìkà tàbí ìwà anìkànjọpọ́n tàbí ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí àwọn tó bá a ṣe. Ìgbà mìíràn, yóò mú u jẹ. Èyí ló wọ́pọ̀ jù nínú àwon ìtàn náà. Ìgbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, yóò sì kẹ́san ìwà ibi rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ẹkùn ṣe fọ́ ọ mọ́ orí àpáta nínú Ìjàpá àti Àtíòro, tí igbá eyin rẹ̀ sì fọ́ yángá-yángá. Àti bí ó ṣe sọ ara rẹ̀ di ẹni tí ò le wọ ìlú mọ́ nínú u Ìjàpá àti àwọn Ẹranko. Pé iye ìgbà tí Ìjàpá mú àwọn ìwà burúkú rẹ̀ jẹ pọ̀ ju iye ìgbà tó jẹ̀yà àwọn ìwà yí fi hàn wá pé òǹkọ̀wé náà polongo ọgbọ́n àrékérekè Ìjàpá ju nǹkan mìíràn lọ nínú ìwé náà. Inú ìtàn kan péré ni Ìjàpá ti lo ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ fún dáadáa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwé tó lárinrin ni.
Kókó-ọ̀rọ̀
- Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́
- Ìgbẹ̀san
- Ìkà
- Ẹ̀tàn
- Ọ̀kańjúà
Ẹ̀dá-ìtàn
- Ìjàpá: Ìjàpá kópa nínú u gbogbo ìtàn ogún náà, òun sì ni olú ẹ̀dá-ìtàn. Ó ní ìwà ìkà, ó ní ọ̀kańjúà, ó láhun, ó sì ní ọgbọ́n àrékérekè tó fi ń yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjọ̀ngbọ̀n tó bá kó ara rẹ̀ sí.
- Yánníbo: Yánníbo ni ìyàwó Ìjàpá. Ó kópa nínú mẹ́fà nínú àwon ìtàn náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, Ìjàpá a máa ṣe ahun sí Yánníbo nípa àwọn èrè tó bá fi èrú kó wálé. Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, wọ́n jọjọ máa ń jẹ ẹ́ ni. A kò lẹ sọ pé ó faramọ́ àwọn ìwà ọkọ rẹ̀ torí nínú ìtan Ìjàpá àti Yánníbo, Yánníbo lòdì sí ọ̀nà èrú tí ọkọ rẹ̀ fi ń kó iṣu wálé, ó sì fún ọkọ rẹ̀ lówó kó fi dá oko tirẹ̀.
- Ìgbín: Ìgbín kópa nínú mẹ́rin nínú àwọn ìtàn náà. Nínú u gbogbo rẹ̀ ni òǹkọ̀wé sì fi hàn pé Ìgbín lọ́gbọ́n lórí ju Ìjàpá lọ. Àti pé, lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, dáadáa ni ó máa ń lo ọgbọ́n tirẹ̀ fún.
- Ẹkùn: Ẹkùn hàn nínú márùn-ún nínú àwọn ìtàn náà. Nínú u gbogbo rẹ̀, àyàfi ọ̀kan, ni Ìjàpá ti fi ojú Ẹkùn rí màbo. A lé fà á yọ láti ibẹ̀ pé òǹkọ̀wé ń gbìyànjú àti sọ pé ọgbọ́n ju agbára lọ.
- Erin: Ẹ̀ẹ̀mẹta ni Ẹrín hàn nínú ìwé náà. Ẹ̀ẹ̀mẹtẹ̀ta ni Ìjàpá fi ọgbọ́n borí i Ẹrin náà, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí i ti Ẹkùn, èyí náà fi hàn pé ọgbọ́n ju agbára.
Àwọn ẹ̀dá-ìtàn mìíràn ni Ajá, Ẹyẹlé, Ọ̀bọ, Adígbọ́nránńkú àti àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan náà.