Ọlọ́runṣògo

Overview

Ọlọ́runṣògo by Sunday Ẹ̀ṣọ́-Olúbọ́rọ̀dé is a novel that follows the stories of Rónkẹ́ and Fẹ́mi, who began their romantic relationship back in grammar school. They decided to marry after completing their education.

However, things took a different turn after their Higher School Certificate (HSC). It was during this time that Rónkẹ́ became obsessed with money. She began entertaining various male admirers, frolicking with “Sugar Daddies.” She turned her back on Fẹ́mi, her faithful friend.

Her immoral lifestyle and greed for money led her to the point of getting pregnant and giving birth to a child without a father.

Book Profile

  • Title: Ọlọ́runṣògo
  • Author: Sunday Ẹ̀ṣọ́-Olúbọ́rọ̀dé
  • Genre: Ìtàn Àròsọ (Prose)
  • Year of Publication: 1991
  • Publisher: Sumob Publishers, Òṣogbo
  • Number of Pages: 165
  • Structure: Orí Méje (Seven Chapters)
  • ISBN: 978-978-31181-0-2
  • Edition: Third Edition (2012)

Availability

  • Available Format: Print (Paperback)
  • Where to Borrow: n/a
  • Where to Buy: You can get the novel in local bookshops in Osogbo, Ibadan, Ife, Ede, Iwo, Ilesa etc.

Brief Description:

“Ṣé ayé sùúrùlérè ni ìwọ ṣì wà táwọn ẹgbẹ́ rẹ wà ní ọlọ́runṣògo? Èmi ò sí lẹ́gbẹ́ sùúrùlérè nítèmi o, ẹgbẹ́ Ọlọ́runṣògo ni mo wà.” Àṣà tó gbòde kan láàrin àwọn ọ̀dọ́bìnrin orílẹ̀-èdè nì yìí. Wọn a ní àwọn kò le bá ọkùnrin kan jìyà. ‘Àfi ọbẹ̀ tó jiná’.

Rónkẹ́ àti Fẹ́mi ni wọ́n jọ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ wọn láti ilé-ìwé Girama. Wọ́n pinnu àti fẹ́ ara wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá kàwé dójú àmì. Lẹ́yìn ìwé ẹ̀rí oníwèé méjìlá (HSC).

Àsìkò yìí ni Rónkẹ́ la ojú àlàsódì sí owó. Nípa ẹgbẹ́ kíkó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní oríṣìíṣìí òrẹ́kùnrin. Ó ń yan ‘Ṣúgá Dadì’. Ó kúrò nínú ẹgbẹ́ sùúrùlérè, ó bọ́ sí ẹgbẹ́ ọlọ́runṣògo. Ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ni Àgbà ní Iléṣà. Ó kọ ẹ̀yìn sí Fẹ́mi ọ̀rẹ́ rẹ̀ àárọ̀. Tajá tẹran wá sọ Rónkẹ́ dohun èlò àlòpatì.

Ìṣekúṣe àti ojúkòkòrò owó ni ó tì í débi tí ó ti lọ gboyún. Ó bí ọmọ tí kò ní bàbá. Fẹ́mi rè é, ó múra síṣẹ́, ó lọ sí Ifáfitì. Ǹjẹ́ kín ni ó gbẹ̀yìn àwọn méjèèjì? Èwo ló pé nínú Sùúrùlérè àti Ọlọ́runṣògo?

Also by the Author

  • Ìyàwó Alárádè
  • Ó Léwu

Alternative Spellings

Here are the alternative spellings, mostly anglicised, of the keywords, having been stripped of their diacritic marks:

  • Olorunsogo
  • Sunday Eso-Oluborode
  • Olorunsogo by Sunday Eso-Oluborode

Reference
Adedeji, Ridwan. (2025). Ọlọ́runṣògo láti ọwọ́ọ Sunday Ẹ̀ṣọ́-Olúbọ́rọ̀dé. Litireso Yoruba. https://litiresoyoruba.com/olorunsogo-lati-owoo-sunday-eso-oluborode/ (Accessed on October 27, 2025 at 23:03)

Similar Entries

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.